0% found this document useful (0 votes)
686 views24 pages

3rd Term j2 Yoruba

The document outlines the curriculum for Yoruba language studies for J.S.S.2 students, covering topics such as letter writing, Yoruba beliefs about Olodumare, and the significance of various Yoruba literary forms. It includes specific assignments and references to educational materials. The document emphasizes the structure and components of letters, as well as the cultural context of Yoruba spirituality and literature.

Uploaded by

roseline18uko
Copyright
© © All Rights Reserved
We take content rights seriously. If you suspect this is your content, claim it here.
Available Formats
Download as DOC, PDF, TXT or read online on Scribd
0% found this document useful (0 votes)
686 views24 pages

3rd Term j2 Yoruba

The document outlines the curriculum for Yoruba language studies for J.S.S.2 students, covering topics such as letter writing, Yoruba beliefs about Olodumare, and the significance of various Yoruba literary forms. It includes specific assignments and references to educational materials. The document emphasizes the structure and components of letters, as well as the cultural context of Yoruba spirituality and literature.

Uploaded by

roseline18uko
Copyright
© © All Rights Reserved
We take content rights seriously. If you suspect this is your content, claim it here.
Available Formats
Download as DOC, PDF, TXT or read online on Scribd
You are on page 1/ 24

Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

E-NOTE SAA KETA

ISE: ISE YORUBA KILAASI: J.S.S.2


1 Atunyewo ise saa keji.
2 EDE Leta gbefe. Ohun ti leta gbefe je, awon ona ti a le gba ko leta gbefe
(deeti, ikini, Ipari).
ASA Igbagbo awon Yoruba nipa Olodumare.
LIT Awon ewi ti a n fi oro inu won da won mo.
3 EDE Apola oruko
ASA Igbagbo ati ero Yoruba nipa orisa.
LIT Kika iwe apileko ti ijoba yan.
4 EDE Apola ise.
ASA Bi awon akoni eda se di orisa akunlebo (Sango, Ogun abbl)
LIT Kika iwe apileko ewi ti ijoba yan
5 EDE Iseda oro oruko ( lilo afomo ibere ati afomo aarin.
ASA Ikini.
LIT Kika iwe apileko ti ijoba yan.
6 EDE Iseda oro oruko (lilo ilana apetunpe).
ASA Igbagbo awon Yoruba nipa iye leyin iku. Bo se suyo ninu asa Yoruba-
Isomoloruko, isinku, akudaaya (abbl).
LIT Awon ewi ti a fi oro inu won da won mo-ofo. Awon igbese-maye, ape
mora, ewu.
7 EDE Leta aigbefe (1) ohun ti leta aigbefe je (2) awon ilana ti a le gba ko le
ta aigbefe-adireesi, deeti,adireesi agbaleta,ikini ibere,koko leta, ipari.
ASA Awon ohun mimo ninu esin ibile- igba funfun,ileke funfun, awo funfun
Ogiri funfun abbl.
LIT Kika iwe apileko ti ijoba yan.
8 EDE Ami Ohun Oro Onisilebu Meji.
ASA Awon Eya Yoruba ati ibi ti won tedo si.
LIT Kikai we Apileko ti Ijoba yan.
9 EDE Atunyewo awon awe gbolohun ede Yoruba ( olori awe gbolohun ati
awe gbolohun afibo)
ASA Asa Isinku ni Ile Yoruba.
LIT Kika iwe apileko.
10 EDE Apola oro aponle ati ise ti eya kookan n se ninu gbolohun (1)
aponle alasiko, (2) aponle onibi (3) aponle onisesi abbl.
ASA Owe.
LIT Kika iwe apieko ti ijoba yan.
11&12 Atunyewo ise saa keta ati idanrawo.

IWE ITOKASI
1 S. Y Adewoyin (2004) New Simplified L1Yoruba iwe keji [J. s. s .2] Copromutt (publishers) Nigeria
Limited
2 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc.
3 Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.3) university Press Plc.
4 Ayo Bamgbose (1990) Fonoloji ati Girama Yoruba Onibon-Oje Press.

OSE KIN-IN-NI

EDE

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 1


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

LETA GBEFE
AKOONU: Leta
Adiresi
Deeti
Ikini ibere
Koko oro
Asokagba
Ikini ipari
Leta kiko ni ona ti a n gba ranse asiri si ara eni. Oun ni o duro fun aroko pipa ranse lode oni. A maa n
fi ero ara eni han ninu iru leta (aroko) yii. Leta pin si orisii meji awon naa ni: leta gbefe ati leta aigbefe. Leta
gbefe ni leta si obi,ore, ibatan ati awon miiran ti o sun moni. Ilana leta gbefe ni: adiresi, deeti, ikini ibere,
koko aroko, ikini ipari.
Kiko adireesi: oke apa otun ni a maa n ko adiresi eni ti o n ko leta si. Adiresi yii maa n ni awon
nnkan wonyi ninu: nomba, adugbo,opopona, ipinle. Fun apeere:
3, Opopona Olowu,
Adugbo Bodija,
Ilu Ibadan.
12-02-2013.

3, Opopona Olowu,
Adugbo Bodija,
Ilu Ibadan,
12-02-2013.

Kiko deeti: leyin ti a ba ko leta tan, a o ko deeti ojo, osu ati odun ti a ko leta. Fun apeere: 22 : 3 :
2011. tabi 22 Erena, 2007.
Ikini ibere: apa owo osi lori ila ti o tele deeti ni a maa n ko eyi si. Fun apeere:
Omo mi owon, Omo mi tooto, Iya mi atata, Ore mi owon, Egbon mi tooto, Tunji mi atata,.
Koko oro: nibi ni a ti maa n ko ohun ti o mu wa ko leta gan-an. Ona meta ni abala yii pin si. Awon
naa ni: ifaara (introduction) aarin (body of the leta) igunle (conclution). Ninu ifaara ni a ti maa ko idi ti a fi
ko leta lerefe tabi ni soki, inu aarin leta ni a ti maa n se alaye lekunrere fun eni ti a ko leta si nigba ti igunle
maa je ibi ti a ti maa se igunle leta wa. Ni abala igunle yii, a le ki eniyan nibe.
Ipari ati oruko akoleta: apa owo osi ni isale ni eyi maa n wa. Fun apeere:
Emi ni omo yin,
Babatunde.

Baba re,
Adewuyi.

Ore re,
Folake.
IGBELWON
1 ko adireesi ile iwe re sile.
2 Se alaye perete lori koko oro leta.

IWE AKATILEWA
Oyembamji Mustapha (2006) Eko Ede Yoruba Titun (s.s.s 1) iwe kin-in-ni. University Press Plc. Oju iwe
17-19.
ASA

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 2


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

IGBAGBO AWON YORUBA NIPA OLODUMARE


Akoonu: igbagbo awon Yoruba nipa Olodumare.
Orisiirisii oruko Olodumare
Ifihan ero Yoruba lori oruko Olodumare
Ohun ti opolopo awon eniyan lero ni wi pe awon Yoruba ko mo Olorun tele afi igba ti awon elesin
Kristi ati awon islam to de. Iro patapata ni eyi. Awon Yoruba ti n sin Olorun ki awon elesin ajeji to de. Lara
awon ohun ti o je ki a mo ni oniruuru oruko ti a n pe Olorun. Oun ni a n pe ni Olodumare tabi
Eledumare,Olu orun,Olorun, Eledaa, Adedaa, Obanjigi, Oba ogo abbl.
Awon yoruba beru Olorun pupo bakan naa ni a si tun bowo fun. Idi niyi ti a ki I fi ku giri lo ba tabi ki
a maa beere nnkan lowo re. Dipo bee a yan awon orisa kan gege bi asoju wa tabi alagbawi wa lodo re. Awon
iru orisa bee ni Ogun, Sango, Orunmila, Obatala abbl. Awon wonyi ni awon Yoruba maa ran si Olorun
nigba ti won ba fe gba nnkan lowo re.
Die lara awon oruko ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olorun ni:
 Olowogbooro
 Eleti gbaroye
 Atererekaye
 Awimayehun
 Olodumare
 Obanjigi
 Olorun
 Olu Orun
 Oba Ogo.
 Kabiyesi
 Jingbinikin
 Arogunmatidi
 Arabaribiti
 Aribirabata.

IGBELEWON
Ko oruko Olodumare marun-un ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olodumare sile.
IWE AKATILEWA
1 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc.oju
iwe 95-97
2 Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.3) university Press Plc.oju iwe 181-18

IFAARA LORI LITIRESO ALOHUN TI A N FI ORO INU WON DA WON MO.


Awon litireso wonyi ki i ni isori kan taara, won o je mo esin bee naa ni won o je mo ayeye lo
ju. Apeere won ni oriki, ofo, ese ifa, itandonwe, oro akonilenu, aalo, ewidowe, ede asiko abbl.
A Oriki Orile (family name/praise): Oriki orile ni ewi alohun ti o da lori baba nla eni ati ibi ti
won ti se wa. Apeere oriki orile ni onikoyi, Oluoje, Oko irese, Ajisola, Erin, Opomulero, Olofa,
Ologbin-in Olufe, Iloko abbl.
B OFO (incantation): Ofo je oro agbara ti awon Yoruba maa n lo pelu oogun. Ofo ni o n fi
igbagbo awon Yoruba han ninu agbara oro. Aarin awon adahunse ati onisegun ni o ti wopo. Awon
nnkan ti a fi maa n da mo ni: A ki i, oro ase, ebe, awitunwi, iforodara, afiwe.
D ESE IFA (ifa divination ): Awon ni oro agbara ti awon onifa maa n lo. Awon babalawo/onifa
ni o maa n da ifa. Awon ti won maa n da ifa maa n wo aso funfun, bata funfun pelu inu mimo.
Awon ohun ti a fi maa n da ese ifa ni: Adia fun, ebo riru, awon oruko emi airi.

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 3


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

E ORO AKONILENU; awon oro ti o soro sare pe ni oro akonilenu. Apeere oro akonilenu ni:
obo n gbe obo gun ope, Alira n lora rela, Mo je dodo nido ma wa fi owo dodo pa omo onidodo ni
idodo.

IGBELEWON
1 Awon ewi alohun wo ni a maa n fi oro inu won da won mo?
2 Ko oriki orile marun-un sile.
3 Salaye perete lori ofo.

IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 55-58 Copromutt
(publishers) Nigeria Limited

APAPO IGBELWON
1 ko adireesi ile iwe re sile.
2 Se alaye perete lori koko oro leta.
3 Ko orisii ewi alohun marun-un ti a n fi oro inu won da won mo.
4 Salaye meta ninu won.
5 Ko oruko Olodumare mejo sile.

ATUNYEWO EKO
1. Ko ewi alohun ajemayeye mewaa sile ati ibi ti okookan ti wopo.

ISE ASETILEWA
1 Leta …….ni leta iwase. (a) ore (b) gbefe (d) alaigbefe.
2 Ibi ti adireesi eni ti a n ko leta si maa n wa ni….. (a) isale leta patapata ni apa osi (b) oke leta ni
apa otun (d) oke leta ni apa osi
3 Adireesi eni ti n ko leta maa n wa ni ….. (a) isale leta ni apa otum (b) oke leta ni apa osi (d) oke
leta ni apa otun.
4 Ewo ni ki i se ara won? (a) oro akonilenu (b) iyere ifa (d) oriki.
5 Ewo ni itan ati oro bi ‘omo’ ti maa n wopo? (a) oro akonilenu (b) iyere ifa (d) oriki.
APA KEJI
1. Ko adireesi ile re sile.
2. Ko awon ewi ti a fi oro inu won da won mo ki o si salaye meta ninu won.

OSE KEJI
APOLA ORUKO
(Phrases)
Apola ni apa kan gbolohun ti o le je oro tabi akojopo oro. Lara apola inu ede Yoruba ni apola oruko, aopla
ise, ati apola aponle.
Apola Oruko (noun phrase): okan ninu apola oro ti a hun po di gbolohun ni apola oruko. Apola Oruko le je:

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 4


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

i. Oro Oruko eyo kan ni ipo oluwa tabi ni ipo abo. Apeere;
Yetunde sun fonfon
Epo wa ni Sapele.
ii. Oro Oruko tabi Akojopo Oro Oruko ti o n sise eyan. Apeere:
Omi kanga maa n lo ni enu.
Ijoba Ibile Somolu ko awon iso wewe.
iii. Oro Oruko ati Eyan Alawe Gbolohun: apeere:
Iyabo ti a n soro re ti de.
Ile ti a fi ito mo iri ni yoo wo.
iv. Aropo Oruko ni ipo oluwa tabi abo ninu gbolohun: apeere:
Mo gba oro naa bee
A ti lo.
Maa ba a wa.
v. Oro Aropo Afarajoruko nipo Oluwa ninu gbolohun.
Emi ti lo o.
Awa pelu iwo ki i se egbe.
Iwo ni mo n ki.
IGBELEWON.
Ko apeere apola oruko marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.

IWE AKATILEWA
S.Y Adewoyin (2003) SIMPLIFIED YORUBA L1 J.S.S.2 Corpromutt Publishers Nig Lld O. I. 23-24.

ASA
IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ORISA
Opolopo eda lo ro wi pe awon Yoruba ko mo Olorun. Opo lo ro wi pe igba ti awon elesin ajeji ni o fi
ye awon Yoruba pe Olorun wa. Eyi ko ri be rara. Awon Yoruba ti mo Olorun ki awon alawo funfun tode.
Eyi han ninu oruko orisiirisii ti won fun Olorun bi Olu orun, Eledaa( eni ti o da gbogbo nnkan), Akoda-Aye.
Bee ni, aborisa ni awon Yoruba, ero won ni wi pe elese ni awa eeyan ti Eledumare si je eni mimo.
Eni kukuru a maa se egbe eniyan gigun bi? Eyi ni o fa ti won fi gbe awon orisa kale gege bi agbode gba
laarin won ati Olorun. Awon orisa wonyi ni won maa n ran lo ba Olorun. Won ki i ku giri lo ba Olodumare.
Nitori naa igbagbo awon Yoruba lori awon orisa wonyi ko kere. Apeere awon orisa naa ni Obatala, Sango,
Oya, Ogun, Osun, Moremi, Esu/Elegbara, Egungun, Orisa Oko, Oro, Gelede abbl.
IGBELEWON
Se alaye perete lori igbagbo awon Yoruba nipa orisa.

APAPO IGBELEWON
1. Ko apeere apola oruko marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.
2. Se alaye perete lori igbagbo awon Yoruba nipa orisa.

ATUNYEWO EKO
1. Ko esin abalye/ibile mejo sile.
2. Ko ewi alohun esin abalaye ti o ko sile.
IWE AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun oju iwe 198-204 University Press

ISE ASETLEWA
1. ..... ni akojopo oro ti ki i ni itumo ninu gbolohun ni (a) apola (b) oro ise (d) akojopo.
2. Apola maa n sise ....... abo ati eyan? (a) oluwa (b) oro oruko (d) oro ise.

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 5


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

3. Ewo ni ki i se ara won? (a) ekun iyawo (b) iyere-ifa (d) Esu-pipe.
4. Agbodegba laarin eniyan ati Olodumare ni (a) Orisa (b) Esu (d) Orunmila.
5. Oriki Ogun saaba maa n jeyo ninu……………(a) sango pipe (b) ijala (d) Iyere
APA KEJI
1. Ko apeere apola oruko marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.
2. ko ewi alohun esin abalaye meji sile

OSE KETA
APOLA-ISE
(verb phrase)
Ninu apola-ise ni koko gbolohun maa n wa. orisiirisii isori oro ni o le jeyo po ninu apola-ise. Apola-ise le
je:
i. Oro-Ise Alaigbabo.
Iji ja
Mo sun
Iyan naa kan
ii. Oro-ise ati oro-oruko ni ipo abo. Apeere:
Dolapo ra keke
Mo je akara.
Femi pari idanwo
iii. Oro-Ise agbabo ati Eyan. (oro aponle). Apeere:
Bola mu oti yo.
Jide gun igi giga fiofio.
Mo rerin-in arintakiti.
iv. Oro-Ise ati Apola Atokun apeere:
Bola lo si Obilende ni ana.
Mo ti ilekun si ita.
v. Eyo Oro-Ise ti o n sise odidi gbolohun. Apeere:
Jade
Jokoo
Dide
IGBELEWON
1. Ko apeere Apola-Ise marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.

IWE AKATILEWA
S.Y Adewoyin (2003) SIMPLIFIED YORUBA L1 J.S.S.2 Corpromutt Publishers Nig Lld O. I. 24-25.

BI AWON AKONI EDA SE DI ORISA AKUNLEBO


Ona meji pataki ni a le pin awon orisa ile Yoruba si. Awon orisa kan wa to je pe
won ro wa lati orun, orisa ni Olorun da won, won ki i se eniyan nigba kan kan ri. Awon
orisa ipin keji ni awon eniyan ti a so di orisa nitori ise ribiribi owo won nigba ti won wa
laye. Awon wonyi ki i se orisa lati orun wa. Apeere awon orisa ti won ro wa lati orun
ni Obatala, Orumila, Ogun, Esu. Awon ti a so di orisa akunlebo ni yemoja, sango, oya,
osun, oba, meremi, orisa oko ati bee bee lo.

MOREMI: Ni asiko kan ti awon igbo n dun mohuru mo awon ara Ile-Ife, Moremi
ni o je je lodo Esinminrin pe oun a fi omo oun rubo si i to ba le ba won segun Igbo to n

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 6


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

du mo won. Leyin eyi won gbogun ti awon igbo naa won si segun. Eyi lo mu ki won so
Moremi di orisa akunlebo leyin iku re.

OGUN( god of iron): Ode ni Ogun ni aye atijo. Tabutu ni oruko iya ogun.Oririnna si ni baba re O
je oye Osinmole ni ile Ife, ki o to lo si ilu ire Ekiti. Mariwo ni aso Ogun, eje lo si maa n mu. Gbogbo ohun to
je mo irin je ti ogun Ogun korira ki won gbe koronfo agbe emu duro. O tun korira iwa eke, iro pipa, ole jija

SANGO (god of lithning & thunder): je okan lara awon oba to ti je ni Oyo ile laye atijo. Gege bi
oba, sango ni agbara, oogun ati igboya, ina si maa n jade lenu re bulabula to ba n soro, Nitori agbara yii o
bere si ni si abgbara lo. Awon ilu wa dite mo nitori asilo agbara re. Idi inyii ti o fi lo pokun so nidi igi aayan
ni ibi ti won n pe ni koso. Oriki sango lo maa n poju ninu sango pipe won maa nlo lati yin-in lati dupe lowo
re bi oba se won loore ati lati be e fun idaabobo, bibo asiri won ati lati beere fun awon nnkan ti won se
alaini. Awon nnkan ti sango n lo gege bi agbara ni ose sango, edun ara ati ina to maa n yo lenu re. Iyawo
meta ni sango ni nigba aye re, oya, osun ati oba, oya wole ni Ira o si di odo ti a mo si odo oya di oni oloni.
Sango korira siga mimu, obi, ewa ati eku ago jije.

IGBELEWON
1. Salaye ona meji ti a pin awon orisa ile Yoruba si.
2. Ki lo so Moremi di orisa akunlebo.

LITIRESO KIKA IWE APILEKO

APAPPO IGBELEWON
1. Ko apeere Apola-Ise marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.
2. Salaye ona meji ti a pin awon orisa ile Yoruba si.
3. Ki lo so Moremi di orisa akunlebo.

IWE AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun University Press oju iwe 198-204

ISE ASETILEWA
1. ‘Ade gun keke’ apola ise inu gbolohun yii ni (a) Ade (b) gun (d) gun keke.
2. ‘Olu ki i ja’ iru apola yii ni ...... (a) oro ise agbabo (b) oro ise alaigbabo (d) ibeere pesije.
3. Apola ise odidi gbolohun ni (a) Jade (b) Olu ki i sun (d) Ola n korin lowo.
4. Orisa wo ni awon Yoruba gbagbo pe o maa n yo ina lenu ………..(a) sango (b) Moremi (d) ogun.
5. Atenumo oro ju eekan lo ninu ewi ni …………. (a) ibeere pesije (b) awitunwi (d) iforodara.
APA KEJI
1. Ko apeere Apola-Ise marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.?
6 ko awon orisa meta ti won di orisa akunlebo nipa agbara.
Ko akanlo ede ayaworan merin ninu iwe apileko pelu alaye.

OSE KERIN
EDE

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 7


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

ISEDA ORO ORUKO


AKOONU:-
__ Afomo ibere
Afomo aarin
NOOTI
Orisiirisii igbese ni a le gbe lati seda oro oruko yato si awon oro oruko ponbele ti a ni ninu ede
Yoruba, sugbon ise kan naa ni gbogbo won n se ninu gbolohun.
AFOMO IBERE
(A) A maa n seda oro oruko nipa fifi afomo ibere mo oro ise kan. Awon wunren afomo ibere ni:-
aeeioo
ae ioo
Ati, on, ,oni, olu
Apeere: -

Afomo ibere Oro ise Oro oruko ti a seda

a bo abo
e be ebe
o ku oku
e gbe egbe
ai lo ailo

(B) A maa n fi afomo ibere mo oro ise meji


Afomo ibere Oro ise (1) Oro (2)Oro oruko ti a seda
I gba gbo Igbagbo
a ko jo Akojo
I tan je Itanje
a be wo Abewo
a pe je Apeje
(D) A maa n fi afomo ibere mo oro ise pelu oro oruko miiran. Isunki maa n waye laarin oro ise
ati oro oruko ti o tele e ki a to wa seda oro oruko tuntun lara afomo ibere ati
isunki.
Afomo ibere Oro ise Oro Oruko Isunki Oro oruko ti a seda
a pa eja peja Apeja
on ra oja raja Oaraja
a de irin derin Aderin
ati gun igi gungi atigungi
Olu wa idi wadii Oluwadii

(E) A maa n fi afomo ibere mo apola oro ise lati di oro oruko miran.
Afomo ibere Apola ise Oro oruko ti a seda
I da eni ni eko Idanilekoo
a ru eru ma so Arerumaso
a pa eni ma yo ida apanimayoda
ai ro inu pa iwa da aironupiwada
ai fi agba fun enikan aifagbafenikan
(E) A maa n fi afomo ibere “oni” mo oro oruko lati seda oro oruko miran.
Apeere:-
Oni + Ile = onile

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 8


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

Oni + aso = Alaso


Oni + oogun = oloogun
Oni + oko = oloko
Oni + igi = Onigi
IGBELEWON
1. Awon ona wo ni a le gba lo afomo ibere lati seda oro oruko.
2. Awon wunren wo ni a n lo gege bi afomo aarin
3. Seda oro oruko merin nipa lilo afomo ibere “oni”
AWON IWE KIKA
1. Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) oju iwe 57-58 Longman
Nig Plc.
2. Oyebamiji Mustapha (2002) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.2) oju iwe 32-36 university Press .

ASA
IKINI (GREETINGS)
Ikini je okan lara asa Yoruba. O je ona ti a fi n gba mo omoluwabi. Yoruba ko fi owo yepere mu asa
ikini. Ti omode ba n koja ni odo agbalagba o gbodo ki won afi ti o ba je wi pe omo naa ko ni eko
ile. Okunrin maa n dobale ki eniyan ni ni igba ti obinrin yoo kunle.
IDOBALE ATI IKUNLE

AKOKO IKINI IDAHUN


Aaro/owuro Ekaaro o o o, a dupe
E e jiire bi o
Osan E kaasan o o o.
Irole E kuurole o oo
Ale E kale o oo

BI A SE N KI NI IKINI IDAHUN
Aboyun Asokale anfaani o e se o
Nibi isomoloruko E ku ijade oni adun a kari o
Nibi oku E ku aseyinde o eyin naa a gbeyin arugbo yin o
Onidiri Eku ewa/oju gbooro oo
Agbe Aroko bodun de o ase o

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 9


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

Osise Ijoba oko oba o ni sayin lese o ami o


Ijoye kara o le wa a gbo.
Oba Kabiyesi o oba n ki o
Eni to n jeun lowo E bamiire o omo rere a ba o je
Nibi oku agba E ku aseyinde o e se o, eyin naa a gbeyin arugbo yin o
Ipo Iloyun afon a gbo ko to wo
A a gbohun iya ati ti omo o
Were ni a o gbo o
Agbe o ni fo, omi o ni danu o

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ
Oyèbámjí Mustapha (2013) ÈKÓ ÈDÈ YORÙBÁ TITUN ìwé kìn-ín-ní University Press Plc oju
iwe 116-120

IGBELEWON
1. Ko ona meta ti a n gba ki awon onise owo meta.

Bawo ni won se n ki (eniyan ni): osan, alaboyun, ogilniti ati eni ti o n jeun lowo.
APAPO IGBELEWON
1. Awon ona wo ni a le gba lo afomo ibere lati seda oro oruko.
2. Awon wunren wo ni a n lo gege bi afomo aarin
3. Seda oro oruko merin nipa lilo afomo ibere “oni”
4. Salaye bi a se n ki awon wonyi: aboyun agbe, osise ijoba, oba

ATUNYEWO EKO
1. Ko gbogbo iro konsonanti sile
2. Ko gbogbo iro faweli sile.

IWE AKATILEWA
1. Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.3) university Press oju iwe 198-200
2. Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc oju
iwe 17.

ISE ASETILEWA
1 A seda “ebe” nipa fifi afomo ibere mo _______ (a) oro ise kan (b) Oro ise meji (d) Oro ise pelu oro oruko
2. Afomo ibere mo oro ise meji ni _______ (a) Ebe (b) Oluwadii (d) Apeje.
3 Oro oruko maa n sise pelu oro ise ninu iseda oro oruko (a) Beeko (B0 Bee ni (d) ko ye mi.
4 igba a ro o ni won maa n ki (a) oba (b) ijoye (d) alaboyun
5 eni ti o maa n dobale ni (a) okunrin (b) obinrin (d) agbe.

APA KEJI
1. Lo awon oro wonyi lati seda oro oruko: oni, ati, e.
2. salaye lekun rere.
OSE KARUN-UN
EDE
ISEDA ORO ORUKO
APETUNPE
(a) Igba, asiko ati onka ni awon oro oruko ti a n seda bayii maa n ba lo ju.
Apeere:-

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 10


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

Osu + osu = osoosun


Odun + Odun = Odoodun
Orun + Orun = Oroorun
Egbe + egbe = Egbeegbe
Mejo + mejo = Mejeejo

(b) A maa n se apetupe oro ise ati oro oruko nipa sise isunki oro oruko ati oro ise naa.
Oro ise Oro oruko Isunki Oro oruko ti a seda
Da eran daran darandaran
Wo ile wole wolewole
Gbe omo gbomo gbomogbomo
Ko ile kole kolekole
Je eyin jeyin jeyinjeyin
A maa n lo afomo aarin pelu apetunpe oro oruko. Awon weren afomo aarin ni “ki, ku, de, ri. Apeere:-
Oro oruko Afomo aarin Apetunpe oro Oro oruko ti a seda
Oruko/Afomoaarin
Eni + ki + eni = enikeni
Ile + ki + ile = ilekile
Ije + ku + ije = ijekuje
Iso + ku + iso = isokuso
Ile + ji + ile = iledeile
Aye + ri + aye = ayeraye

IGBELEWON
Se itupale awon oro wonyi:
Enikeni, ijokijo, jagunjagun, pejapeja, gbomogbomo.

IWE AKATILEWA
Oyebamiji Mustapha (2002) EKO EDE YORUBA TITUN iwe keji (J.S.S.2) University Press oju iwe 37-39 .
S. Y Adewoyin (2004) New Simplified Yoruba L1 iwe keji [J. s. s .2] Copromutt (publishers) Nigeria oju
iwe 37-38 Limited.

ASA
IGBAGBO AWON YORUBA NIPA IYE LEYIN IKU
Iranse Olodumare ni iku je. Oun ni Olodumare n ran lati pa mu eniyan. Gbese ni iku ko si eni ti ko ni ku.
Irinajo ni iku si orun. Leyin iku, awon Yoruba gbagbo pe iye wa leyin iku. Awon ohun ti o fi idi re mule ni
wonyi:
Odun Eegun: Awon Yoruba gbagbo wi pe egungun je ara orun. Won maa n sin esin egungun fun
iranti baba won ti o ti ku.
Asa Isomoloruko: bi baba tabi iya agba ba ku, awon Yoruba maa n so omo won ni oruko bi
Babatunde, Yetunde, Yejide lati fi han pe ajinde wa.
Asa Ikini: Paapaa nibi isinku agba, won a ni *baba wa somo* won gbagbo pe eni to ku yoo tun jinde
ni orun was aye.
Akudaaya: awon wonyi ni awon ti won ti ku ti won o tun farahan ni ibomiran. Iru awon eeyan bayi
ni won gbagbo pe ojo iku won ko I ti I pe. Won le fe iyawo ki won tun bi omo nibo miiran.
IGBELEWON
So oruko marun-un ti o fi han pe iye wa leyin iku
IWE AKATILEWA

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 11


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.2) University Press oju iwe 105-110.
S. Y Adewoyin (2004) New Simplified Yoruba L1 iwe keji [J. s. s .2] Copromutt (publishers) Nigeria
Limited oju iwe 53-55
LIT
AWON EWI TI A FI ORO INU WON DA WON MO
AKOONU: Oriki.
Ofo.
Iyere Ifa.
Awon litireso atenudenu ti a n fi oro inu won won da won mo ni: Oriki, ofo, Iyere Ifa.
ORIKI-ORILE: ni ami ti o n toka idile eniyan kookan to je abinibi omo Yoruba. Awon iran ti a n ki omo
Yoruba mo ni (oriki orile): onikoyi, Oluoje, Oko irese, Ajisola, Erin, Onikoyi, Olofa, Ologbin-in, Aresa,
Olokun-esin, Alaran-an, Aagberi, Ijamogbo, Olufe, Iloko, Osunlakesan, Ijese. Awon ohun ti a gbo ninu oriki
ni: ( orirun iran, irisi iran,esin iran, ise iran, Aleebu.
OFO: Ofo je oro enu ti o ni agbara ase ninu. Oun lo fi igbagbo awon Yoruba ninu agbara oro han. Bi a se le
da ofo mo.
Oruko eroja oogun: itun lo ni e fi ohun rere tun mi se
Ifa lo ni e fa mi mora……
Lilo apola: a ki i…..
Ki i…….
Alaye fun awijare: Alara se tire, o gun
Ajero se tire o ye….
Awimayhun/ase: Ohun ta wi fun ogbo
Oun ogbo n gbo…..
Lilo oro ebe: ela iwori
Ma je n ri abo ota mi…..
IFA: Orunmila ni awon Yoruba n pe ni akerefinsogbon. Awon babalawo ni won n te ifa. Bi a se le da ese ifa
mo.
A dia fun
O dia fun
O pawo lekee
Ebo riru
Itan
Ewa ede
IGBELEWON
1. Daruko awon oriki orile marun-un.
2. awon nnkan wo ni a fi maa n da oriki mo?

APAPO IGBELEWON
1. Se itupale awon oro wonyi:
2. Enikeni, ijokijo, jagunjagun, pejapeja, gbomogbomo.
3. So oruko marun-un ti o fi han pe iye wa leyin iku
4. Daruko awon oriki orile marun-un.
5. awon nnkan wo ni a fi maa n da oriki mo?

ATUNYEWO EKO
1. Ko ilana asa igbeyawo mejo sile.\
2. Salaye awon igbese naa.

IWE AKATILEWA
Oyebamiji Mustapha (2006) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.3) University Press oju iwe 44-51.

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 12


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

S. Y Adewoyin (2004) New Simplified Yoruba L1 iwe keji [J. s. s .2] Copromutt (publishers) Nigeria
Limited oju iwe 39-43
Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc oju iwe 16.

ISE ASETILEWA
1. Nipase _____ ni a seda “odoodun” (a) Sise apetunpe oro ise ati oro oruko (b) Sise apejuwe oro oruko (d) Lilo
afomo ibere mo oro ise kan.
2. Sise apetunpe oro ise ati oro oruko la fi seda _______ (a) Egbeegbe (b) Oja [d) Arerumaso.
3. Oro oruko maa n sise pelu oro ise ninu iseda oro oruko (a) Beeko (B0 Bee ni (d) ko kan mi.
4. Ewo ninu awon wonyi ni o fi han pe iye wa leyin iku? (a) Romoke (b) Ajagbe (d) kosoko.
5. Inu awon oro wo ni a ti maa n gbo awon oro bi ewe ati egbo? (a) ofo (b) ifa (d) oriki.
APA KEJI
1. Ko oriki ara re sile.
2. Ko oruko meta ti o fi han pe iye wa leyin iku sile.

OSE KEFA

EDE
LETA AIGBEFE
Akoonu:
 Leta aigbefe
 Igbese kiko leta aigbefe
Leta aigbefe je leta ti ko gbefe rara, ti a n ko si eni ti o wa ni ipo tabi aaye owo. O le je leta iwase,
leta ifisun, leta igbaaye lenu ise, leta si ijoba ibile. Igbese meje ni a ni lati tele bi a ba fe ko leta aigbefe.
Awon naa ni:
 Kiko adireesi akoleta
 Kiko deeti ( ojo, osu ati odun ti a ko leta)
 Ipo ati adireesi eni ti a ko leta si
 Ikini ibere leta
 Akole leta
 Koko oro inu leta
 Ipari ati oruko akoleta
Kiko adireesi akoleta: bakana ni eleyi ri pelu leta gbefe.
Kiko deeti: eleyi naa ko fi bee yato si ti leta gbefe. 22/3/2011., 22 Erena, 2011.
Ipo ati adireesi eni ti a ko leta si: apeere iru ipo ati adireesi ni eyi:

3, Opopona Olowu,
Ibudoko Adeyanka,
` Abule Egba
Eko.
11-04-2011

Oga Agba,
Good Shepherd Schools
3, Opopona Olayinka,
Meiran,

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 13


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

Ilu Eko.
Ikini Ibere: Apa owo osi leyi maa n wa bi I ti leta gbefe, sugbon oun ki I fi ipo ti akoleta wa si eni ti
a ko leta si han. Apeere: Alagba, Oga, Madaamu, Olootu abbl.
Akole Leta: ibi yii ni akoleta ti maa n ko akole koko idi ti o fi ko leta gan-an. Apeere:
ITORO AAYE LATI MA WA SI SI ILE EKO
TABI
Itoro Aaye Lati Ma Wa Si Ile Eko
Koko Oro Inu Leta: gege bi a ti so pe leta aigbefe ni eyi. Ko si aaye awada ninu iru leta yii. Ibi
koko oro ni lo ni kiko taara. Ki a ranti pe abala meta naa ni eyi pin si bi I ti leta gbefe: ifaara, aarin ati
igunle.
Ipari ati Oruko Akoleta: ni ipari leta ni owo otun ni eyi maa n wa bi i ti leta gbefe sugbon awon oro
ti a maa n ko yato si ti leta gbefe. Kotan sibe, akoleta maa n bu owo lu leta aigbefe leyin eyi ni yoo ko oruko
re. Apeere:
Emi ni tiyin ni tooto,

`Olasare Adegbagi.

Emi ni,

Kunle Osepotu.
IGBELEWON
1. Ko adireesi ile yin sile pelu deeti
2. Ko adireesi ijoba ibile re sile
3. Ko leta lori akole yii sile. Ko leta si oga ile iwe re *lori idi ti o fi wa si ile iwe ni ana.*
4.
IWE AKATIWA
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun (J.S.S.1 )oju iwe 185-190 University Press Plc.
Oyembamji Mustapha (2006) Eko Ede Yoruba Titun (s.s.s 1) iwe kin-in-ni. University Press Plc. Oju iwe
16-17.

IGBELEWON
5. Ko adireesi ile yin sile pelu deeti
6. Ko adireesi ijoba ibile re sile
7. Ko leta lori akole yii sile. Ko leta si oga ile iwe re *lori idi ti o fi wa si ile iwe ni ana.*

ASA
AKORI ISE: AWON OHUN MIMO NINU ESIN IBILE
AKOONU
- AWON ESIN IBILE TABI ESIN ABALAYE
- AWON OHUN MIMO NINU ESIN IBILE
- OHUN TI AWON ORISA DURO FUN

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 14


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

Orisiirisii esin ni awon baba nla wa n sin ni aye atijo ki awon oyinbo alawo funfun to mu awon esin igbalode
wa saarin awa Yoruba nitori pe won ro pe a ko mo nipa Olorun rara. Olorun ni a n sin ninu gbogbo esin
abalaye tabi esin ibile Yoruba, sugbon ona ti onikaluku n gba sin-in lo yato si ara won. Ni aye atijo, awon
orisa bi i ifa, sango, obatala, esu, oro, egungun, ogun, oya ati bee bee lo ni awon baba wa maa n bo, awon
orisa wonyi lo duro gege bi abenugo laarin awa eniyan ati Olorun, Olorun yii si je mimo idi niyi ti a fi maa n
pe ni Olorun mimo. Niwon igba to si je pe Olorun mimo ni a n sin, awon ohun mimo ni ona mimo kole fara
sin ninu esin abalaye wa.
Niwon igba to je pe Olorun mimo ni a n sin nipase awon orisa wonyii, ohun mimo akoko ni ojubo awon
orisa gbogbo. Mimo ni o gbodo maa wa ni gbogbo igba, ko gbodo si ohun eeri tabi idoti kankan nibe rara,
ayika ibe gbodo mo tonitoni.
Eni to duro gege bi oludari tabi asoju awon olusin ni a n pe ni Abore tabi Aworo Orisa, oun paapaa gbodo
maa wa ni mimo ninu iwa ati ise re ko ma ba a si idena ninu esin won, nitori oludari ni awon olusin yoo ma
fi se awokose. Oro ti yoo maa jade lenu re paapaa gbodo je rere, idi niyi ti won fi maa n so pe “A kii gbo
buburu lenu abore.
Awon ohun elo ti a fi n bo awon orisa paapaa tun je afihan ohun mimo ninu esin abalaye. Awon ohun elo ti
a fi n bo awon orisa yii kii se ohunkohun ti a ba ri tabi awon ohun ti a je ku. Ti won ba fe bo awon orisa yii,
to ba je orisa ti won n fi isu bo ni, iru isu bee gbodo je eyi to dun wo loju. Fun apeere, omi je okan pataki
ninu ohun ti a fi n bo orisa. Omi yii gbodo je eyi to mo lolo, eni ti yoo pon iru omi bee naa gbodo wa ni
mimo, nitori idi eyi ni won se maa n lo odobinrin to ko tii mo okunrin lati pon iru omi bee tabi obinrin to ti
kuro lowo omo bibi ki ohun gbogbo le je mimo. Iru omi bayii ni won n pe ni omi-ajifowuro-pon
Omi ti a ji pon ni aaro kutukutu ni a maa n pon omi ti a ba fe lo nidi orisa nitori omi ajipon la gba pe o je
mimo ju nitori enikeni ko ti de odo naa lati ba a je, eni to ba si lo pon-on aso funfun ni o gbodo wo, ko si
gbodo soro si enikeni. Ojoojumo ni won maa n pon iru omi yii.
A tile gba wi pe awa eniyan gbodo wa ni mimo ninu iwa, isesi, oro ati ero wa ki a to le ri oju rere
olodumare, nnkan funfun si ni Yoruba saba ma fi n se apeere nnkan mimo.
Ko tan sibe, won maa n lo awon nnkan bi igba funfun, ileke funfun bakan naa ni won maa lo aso funfun.
Gbogbo eyi fi iha ti awon Yoruba ko si Olorun han nipe eni mimo ni.
IGBELEWON
1. Awon nnkan wo loje mimo ninu esin abalaye
2. Daruko mefa ninu esin ti awon baba nla wa n sin laye atijo
3. Kini ohun ti a won orisa duro fun larin awa eniyan ati Olorun
4. Iru awon eniyan wo lo maa n pon omi idi oosa.

IWE AKATIWA
Oyebamji Mustapha (2006) Eko Ede Yoruba Titun University Press Plc oju iwe 120-127.
S. Y Adewoyin (2004) New simplified L1Yoruba iwe keji [J. s. s .2] oju iwe 71-72 Copromutt (publishers)
Nigeria Limited.

LITIRESO

KIKA IWE LITIRESO

APAPO IGBELEWON

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 15


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

1. Ko adireesi ile yin sile pelu deeti


2. Ko adireesi ijoba ibile re sile
3. Ko leta lori akole yii sile. Ko leta si oga ile iwe re *lori idi ti o fi wa si ile iwe ni ana.*
4. Awon nnkan wo loje mimo ninu esin abalaye
5. Daruko mefa ninu esin ti awon baba nla wa n sin laye atijo
6. Kini ohun ti a won orisa duro fun larin awa eniyan ati Olorun
7. Iru awon eniyan wo lo maa n pon omi idi oosa.
8. Salaye ona meji ti a le gba ya ofo yato si oro geere

IGBELEWON
1. Salaye igbeyawo aye ode oni.
2. Ko iyato merin laarin igbeyawo aye atijo ati aye ode oni.

IWE AKATIWA
Oyebamji Mustapha (2006) Eko Ede Yorba Titun University Press Plc oju iwe 50-51.

ISE ASETILEWA
1. Leta …….ni leta iwase. (a) ore (b) gbefe (d) alaigbefe.
2. Ibi ti adiresi eni ti a n ko leta si maa n wa ni….. (a) isale leta patapata ni apa osi (b) oke leta ni apa
otun (d) oke leta ni apa osi
3. Adiresi eni ti n ko leta maa n wa ni ….. (a) isale leta ni apa otun (b) oke leta ni apa osi (d) oke leta
ni apa otun.
4. ______ni ohun mimo akoko ninu esin abalaye. (a) ojubo (b) ile aworo (d) omi orisa (e) eni to n
pon omi.
5. Okan ninu awon wonyi lo maa n pon omi orisa. (a) Odomokunrin (b) obinrin to n toju omo lowo (d)
Aworo (e) Omobinrin ti ko ti mo okunrin
6. Idaji ni a maa n pon omi orisa nitori ______ (a) omi bee lo mo ju (b) A ko fe komi tan lodo (d)
Aworo feran iru omi bee (e) A ko fe ki o damu lona
APA KEJI
1. Ko adireesi ile re ati adireesi ijoba ibile re sile.
2. ko awon mimo meta sile ninu awon ohun mimo esin ibile Yoruba sile.

OSE KEJE

EDE
AMI OHUN ONISILEBU MEJI
(fi ara bale daadaa pe awon oro wonyi pelu ami ori won)
AMI OKE AMI ISALE AMI AARIN
sibi iji ife
Kunle igba omo
Wale ego ire

Batani kin-in-ni re mi
(fi ara bale daadaa pe awon oro wonyi pelu ami ori won)
awo ile ise ipon
ile itun aja apa
aje ede egbe ere
ewe ibi imi odo
ogbo oro oso ose

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 16


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

Batani keji re do
(fi ara bale daadaa pe awon oro wonyi pelu ami ori won)
aba ajo ida imo
aje ila ola ife
ere iko ibe amo

are ile iwi ige


Batani keta do mi
(fi ara bale daadaa pe awon oro wonyi pelu ami ori won)
egbe ore opa ota
ila otun aba ada
ilu agba Aja ala
ana apa ara amo

Batani kerin do do

(fi ara bale daadaa pe awon oro wonyi pelu ami ori won)

ebe ese eje efe

ele ala aja apa

ija ila ifa ika

Batani karun-un do re

(fi ara bale daadaa pe awon oro wonyi pelu ami ori won)

ida Dada aga obo

ajo ole obe oje

ope owe.
ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ
Oybamji Musstapha (2013) EKO EDE YORUBA TITUN J.S.S.1 University Press Plc. Oju iwe 91-
99.

IGBELEWON
1. Fi ami si awon oro wonyi lori: ile, ile, ile, aso, aso, ise, ise.

Ko ohun elo inu ile mewaa sile ki o si fi ami si won lori.

ASA
ÀWON EYA YORÙBÁ ÀTI IBI TÍ WÓN TÈDÓ SI
A gbo pe Okanbi ni apele re n je Ide-ko-se-e-ro-aake ni omo kan soso ti o bi. Okunrin ni sugbon
meje ni awon omo Okanbi. Obinrin meji ni Okanbi koko bi awon marun-un yooku si je okunrin.
GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 17
Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

Owu ni omo re akoko. Oun ni o se awon Owu do. Omo re keji ti o je obinrin ni Alaketu, oun ni o sit
e awon Ketu do. Awon woni won n gbe n iha ariwa ile Olominira Binni.
Omo re keta ti o si je okunrin ni o tea won Edo sile. awon wonyi ni o n gbe ipinle Edo lonii. Omo
kerin karun-un ati ekefa ti won je okunrin ni Orangun, Onisabe, ati Olupopo. Eyi ti o si abikeyin ni
Odede ti apele re n je Oranmiyan. Oun ni a gbo pe o tea won Yoruba Oyo sile. akoni Odede. Ise ode
ati jagunjagun ni o n se.
Lojo kan ni o pe awon egbon re pe ki ki awon lo gba esan iku to pa baba won (Lamurudu) ati ile
esin ti le baba won niluu Meka. Awon egbon re ko lo sugbon nitori pe o je akoni, o lo.
Sugbon o ba isoro pade loju ona. Ko le de Meka itiju yii ko je ki o pada de Ile-Ife. Dipo bee o tedo
si ilu ibomiran. Ilu yii in a mo si Oyo. Oyo ni o si n gbe ja awon ilu miiran logun ti o si n gba won
mora. Nipa bayi o di wi pe ilu Oyo bere si nip o si.
Itan miiran ti a tun bo lati enu Alufa Johnson so pe nigba ti Okanbi ku, awon omo re ti won je
okunrin ati obinrin pin ohun ini re sebi eniyan ba dagba omo eni ni i jogun eni.
Oba Ibini jogun owo
Orangun jogun aya.
Onisabee jogun eran-osin
Onipopo jogun ileke
Olowu jogun aso/ewu
Alaketu jogun ade
Aburo won patapata ko si nile won ti pin gbogbo ogun tan ki o de. O sise ode lo. Oba Bini lo tedo si
ipinle Edo. Orangun, Onisabe, Olupopo, Alaketu lo tedo si ibi ti awon omo won wa lonii.
Bi o ti le je pe omo iya ni gbogbo omo kaaaro-oo-jiire, sibe won pin si orisiirisii eya ti ede won si
yato diedie si ara won. Orisii ede ti won n so naa ni eka-ede. Sugbon sa, gbogbo omo Yoruba ni o
ni ede ajumolo kan ti a le pe ni ojulowo Yoruba ede ajumolo. Ede eya Yoruba Oyo ni o sunmo
ojulowo Yoruba naa bi o ti le je wi pe ohun naa ni aleebu tire gege bi eka-ede. Ojulowo Yoruba naa
tabi Yoruba ajumolo yii ni a fi n ko omo ni ile eko. ohun ni a fi n ko orisiirisii iwe lati ori leta si ara
eni titi de ori iwe ti a n ka.
Ipinle meje ni o je ipinle Yoruba ni orile-ede Naijiria, ni abe awon ipinle yii ni a ri awon eya Yoruba
miiran pelu eka ede ti o yato si ara won. Apeere awon ipinle naa ni: Ipinle Oyo, Eko, Ogun, Osun,
Ondo, Ekiti ati Kwara. Ni abe ipinle Ogun ni a ti le ri: Egba, Egbado/Yewa, awori. Ni abe Oyo a ri
eya ...........

ÈYÀ YORÙBÁ ÌLÚ ABÉ WON


Oyo Òyó, Ògbómosó, Ibadan ....
Egbado/Yewa Ilaro, Ado odo, Imeko, Igbogila
Egba Abeokuta, Gbagura, Owu, Oke ona
Ijebu ìjèbú-ode, ìjèbú igbo, àgo ìwoyè,
sàgamu, ìperu, epe
Ilesa ìjèbú ijèsà, ibokun, èsà okè, ipetu ijèsà

IGBELEWON:
 Ko ilu Yoruba mewaa otooto.
 Fi eka ede wonyi tun awon ede Yoruba ajumolo yii: (Ibarapa, Ekiti, Ijebu): ori, imu, enu, eko ati isu.

IWE AKATILEWA
Oyembamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun (J.s.s 1) University Press Plc. Oju iwe 53-62.

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 18


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

LITIRESO

KIKA IWE TI IJOBA YAN

APAPO IGBELEWON
1. Se alaye lekun rere lori ami ohun ede Yoruba pelu apeere mejimeji fun okookan.
2. Ko eya Yoruba mejo sile.

IGBELEWON
1. Ko asa yoruba mewaa sile.
2. Salaye eyo kan ninu asa yoruba ti o ko sile.

IWE AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yorba Titun (J.S.S.1) oju iwe 12-13 University Press Plc.

ISE ASETILEWA
1. Leta …….ni leta iwase. (a) ore (b) gbefe (d) alaigbefe.
2. Ibi ti adiresi eni ti a n ko leta si maa n wa ni….. (a) isale leta patapata ni apa osi (b) oke leta ni
apa otun (d) oke leta ni apa osi
3. Adiresi eni ti n ko leta maa n wa ni ….. (a) isale leta ni apa otun (b) oke leta ni apa osi (d) oke
leta ni apa otun.
4. ______ni ohun mimo akoko ninu esin abalaye. (a) ojubo (b) ile aworo (d) omi orisa (e)
eni to n pon omi.
5. Awon ti o maa n pe ‘ori’ ni eri ni. (a) Eko (b) Ondo (d) Ibarapa (e) Ikeja.
6. Awon ti won maa n pe ‘isu’ ni ‘usu’ ni (a) Eko (b) Ondo (d) Ibarapa (e) Ijesa.

APA KEJI
3. Ko adireesi ile re ati adireesi ijoba ibile re sile.
4. Salaye lori eka ede ati ede ajumolo pelu apeere.

OSE KEJO

EDE
ATUNYEWO AWON AWE GBOLOHUN
Awe gbolohun ni apakan odindi gbolohun. Awe gbolohun pin si orisi meji. Awon naa ni awe gbolohun
afrahe ati olori awe gbolohun.
Olori Awe Gbolohun: Olori awe gbolohun ni abala apakan odindi gbolohun ti o le da duro pelu itumo.Fun
apeere.
 Mo ti lo ki ore mi de
 Gbogbo ilu gbo pe oba waja
 Akekoo naa mura ki o le gbebun
Awe Gbolohun Afarahe: Awe gbolohun afarahe je awe gbolohun ti ko le da duro pelu itumo. Omaa n fara
he olori awe gbolohun ni. Fun apeere.
 Ore mi ti o lo si Eko ti de.
 Mo ti lo ki ore mi to de.
 Mo we nigba ti mo setan
 Awon eniyan mo pe ounje won.

IGBELEWON

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 19


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

1 Toka si olori awe gbolohun nihin-in


 Maa jeun bi mo ba se tan
 Tolu a ti lo ki o to de
 Ounje yii dun bi I pe ki n je tan
 Bade ri mi nigba ti mo de
 A tete lo ki a le tete de
2 Tokasi awe gbolohun afarahe ninu awon gbolohun wonyi
 Oluko ri Dada ni oko oloko
 Mo we nigba ti mo ti oko de
 Bola mura sise ki o le yege
IWE AKATILEWA
1 Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J S S 2 ) oju iwe 29-32 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba

ASA
ASA ISINKU NI ILE YORUBA
Awon Yoruba gbagbo pe gbogbo wa ni a da agbada iku,won a ni ‘ma forum yo mi gbogbo wa la jo
n lo.’atomode atagba ko si eni ti ko ni ku,gbogbo wa la je gbese iku.Ki Olorun ko fi iku rere pa ni.
Awon Yoruba gbagbo pe bi eniyan ba ku yoo lo si orun, yala rere tabi orun apaadi.

AWON ONA TI A N GBA SIN ORISIIRISII OKU.


Ki Edumare ki o fi iku ire pa gbogbo wa bi a ti n sin oku kookan da lori eni ti o je ati iru iku ti o
pa eni bee. Die ninu iru re niwonyii.
Eni ti sango pa. Awon mogba nii se etutu sisin re.
Eni ti sanponna pa inu igbo ni won maa n sin-in si awon adahunse ni
Si n se etutu sisin re.
Eni ti o ku sinu odo eti odo ti o ku si ni won maa n sin–in si, awon
alawo ni si n se etutu re.
Eni ti o ku toyuntoyun awon oloro nii se etutu sisin re.
Adete awon ogbontarigi adahunse ni i se etutu sisin re, inu
Igbo ni won a sin-in si, won a si sun gbogbo nnkan
Ini re.
Eni ti o pokunso Awon onimole ni i sin in,idi igi ti o pokunso si naa
ni won o sin in si.
Abuke Awon babalawo ati adahunse ni i se etutu sinsin re,
Inu igbo ni won sin in si, ninu ikoko,won a si sin
Gbogbo nnkan ini re mo pelu.
Babalawo awon agba awo ni i se etutu sisin oku babalawo
pelu eye ti o ga ti won yoo fi se etutu lati yose re
kuro ninu egbe awo.
Ode awon ode nii se ayeye oku ode sisin,oro Pataki ti
Won ni lati se fun un ni sisipa ode ti a mo si ‘ ikopa ode’ eyi ni
etutu ti won maa n se ki awon eran ti ode naa ti pa nigba aye re
ma baa hun un,ki o sile je ki awon ode to ku laye maa ri eranko.
Onilu awon onilu nii se etutu onilu lati yowo elegbe won
ti o ti ku kuro ninu egbe ki awon to ku le maa ri se.
Alagbede Awon alagbede nii se oro igbeyin fun oku alagbede
lati yowo re kuro ninu egbe.Inu ile aro ti alagbede

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 20


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

naa ti n sise ki o to ku ni a ti maa n saba se etutu


Ikeyin yii.
Yato si gbogbo awon wonyii,awon Yoruba a maa ro oku paapaa eyi ti o ba je oku oroju ti
won gba pe iku re kii se lasan,awon agba adahunse tabi oloogun ni o maa n ro oku, ki
won to gbe e si koto, riro yii lo maa je ki o se iku pa eni ti o pa a. .

IGBELEWON : -
1. salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; - i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete, iv.
Eni ti o pokunso.

IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo,Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Oju iwe 1-35
Corpromutt (Publishers) Nigeria Ltd.

APAPO IGBELEWON
1 Toka si olori awe gbolohun nihin-in
 Maa jeun bi mo ba se tan
 Tolu a ti lo ki o to de
 Ounje yii dun bi I pe ki n je tan
 Bade ri mi nigba ti mo de
 A tete lo ki a le tete de
2 Tokasi awe gbolohun afarahe ninu awon gbolohun wonyi
 Oluko ri Dada ni oko oloko
 Mo we nigba ti mo ti oko de
 Bola mura sise ki o le yege
LITIRESO
IGBELEWON
1. Ko ise abinibi mewaa sile.
2. Slaye okna ninu ise abinibi ti o ko.

KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN.


IWE AKATILEWA
1 Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) oju iwe 10- 15 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

ISE ASETILEWA
1 Ewo lo kun ju lati gbe ero okan eni kale? (a) oro (b) awe gbolohun (d) gbolohun.
2 Ewo ni ki I se orisii gbolohun Yoruba (a) olopo oro ise (b) alakanpo (d) alatunto
3 Awe gbolohun wo lo le da duro bi odidi gbolohun (a) olori (b) afarahe (d) asaponle.
4 Ewi alohun ajemayeye ni (a) ijala (b) dadakuada (d) Oku pipe.
5 Eni ti won maa n sin pelu eru/gbogbo awon nnkan ti o ni ni? (a) adete (b) abuke (d) alawo
APA KEJI
1. Iyato wo lo wa laarin awe gbolohun afarahe a ti olori awe gbolohun? Fun ni apeere meta
2. Salaye bi won se n sin orisii oku marun-un.

OSE KESA-AN

EDE
APOLA APONLE

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 21


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

Oro aponle ni awon oro tabi akojopo oro to n sise aponle fun oro ise. Apeere oro aponle ni daradara,
kiakia, foo. Orisiirisii oro aponle ti ani ninu ede Yoruba ni: apola aponle oniba, apola aponle alasiko, apola
aponle onibi, apola aponle onidii, apola aponle alafiwe.
Apola Aponle Oniba: Apola aponle yii maa n toka si isesi, iba tabi bi a se n se nnkan ninu
gbolohun. A le lo wuren ibeere *Bawo ni* fun irufe awon gbolohun wonnyi. Fun apeere:
Pupa foo
Tutu nini
Ga fiofio
Ara baba naa ya diedie
Igi agala naa ga fiofio.
Apola Aponle Alasiko: Gege bi oruko re se ri ni. Awon wonyi ni i se pelu asiko (time). Wuren
ibeere ti o wulo fun eleyi julo ni * igba wo ni*. Fun apeere:
Teni n bo ni ola
Efo ki I po ni eerun
Wa bi o ba di ale
N o wa ri o bi mo ba setan
Dolapo yoo lo si Oke Oya bi o ba gba olude olojo gbooro.
Apola Aponle Onibi: Iru apola aponle yii ni o n toka si ibi (place). Wuren ti a le lo fun eleyi ni *ibo,
ibo ni*. Fun apeere:
Oloselu naa wa ni ewon (lewon)
Awon akekoo wa ni kilaasi
Kola wa ni Ibadan.
A bi Olu ni Eko
Apola Aponle Alafiwe: Apola aponle alafiwe ni a maa n lo lati fi nnkan kan we ekeji re ninu
gbolohun, (bi/bii) ni o maa n se atoka won. Fun apeere.
O n se bi omugo
Biola n soro bi ologbon
Awon eniyan po repete bi i yanrin
Omo ile-iwe n gbese kemokemo bi i oga ologun.
Apola Aponle Onidii: Eyi ni o maa n toka si idi ti isele inu gbolohun da le lori. Eleyi ni o maa n
toka si idi ti nnkan kan se sele ninu gbolohun. Tori/nitorii ni o maa bere aponle oro aponle lopolopo igba inu
gbolohun.
A n fe iyawo nitori omo
E huwa nitori ola
Sade n lo si yunifasiti tori imo
Mo fe jeun tori ebi.
Apola Aponle Onikani: Apola oro aponle yii maa n gbe oye ‘ ki a ni ‘ jade ninu gbolohun ni.
Oga yoo sebe bi o ba ri owo gba
A o ba dupe bi baalu ba fo
Agbe yoo jo igbo naa raurau.
IGBELEWON
A Fi oro-aponle to ba ye di alafo inu gbolohun wonyi:
1. Ile iya agba mo……….
2. Aja naa feju…………..
3. Igi agbon ga ………….ninu igbo.
4. Aja fo………… mo olowo re.
5. wu ……. . bi i buredi olomi.
B Fa si idi apola aponle nihin-in:
1. A a bi ile bas u
2. Ile Akede wa ni Ibadan.

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 22


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

3. Olu fe e nitori ewa


4. Mo gba a tayotayo
5. lo kiakia.
IWE AKATILEWA
Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) oju iwe 128-132 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

ASA
OWE
Owe ni awon oro ti itumo won jinle ninu asa. Won maa n jeyo ti a ba n so nipa asa Yoruba
kan. Bi apeere:
ASA IGBEYAWO
Bi aya ba moju oko tan, alarina a yeba
Obe ti bale ile ki i je iyaale ile ki i se
Eni fun ni lobinrin pari ore.
ASA ISOMOLORUKO
Ile laawo ki a to somoloruko.
Agba ki I wa loja ki ori omo tuntun wo.
Oruko omo ni ijanu omo.
Ti oko ba mo oju aya tan alarina a yeba
IFOWOSOWOPO
Ajeji owo kan o gbe eru dori.
Owo omode ko to pepe, ti agbalagba kan ko wo keregbe.
Gba mi lojo, ki n gba o leerun.
IGBELEWON
1 Pa owe meta ti a lo fun ifowosowopo.
2 Pa owe meji ti a le ri nibi igbeyawo.

AKATILEWA
1 New simplified Yoruba L1 iwe keta oju iwe 68-69 lati owo S.Y Adewoyin

APAPO IGBELEWON
A Fi oro-aponle to ba ye di alafo inu gbolohun wonyi:
1. Ile iya agba mo……….
2. Aja naa feju…………..
3. Igi agbon ga ………….ninu igbo.
4. Aja fo………… mo olowo re.
5. wu ……. . bi i buredi olomi.
B Fa si idi apola aponle nihin-in:
6. A a bi ile bas u
7. Ile Akede wa ni Ibadan.
8. Olu fe e nitori ewa
9. Mo gba a tayotayo
10. lo kiakia.
D. Pa owe ti o je mo as igbeyawo, ifowosowopo, igbeyawo ati isomoloruko.

IGBELEWON
1. Ko ona mejo ti a gba ran ara wa lowo.
2. Salaye meta ninu awon asa iranra-eni-lowo.

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 23


Oruko: ........................................................................................... Kilaasi: ........................

AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 44-50 Copromutt (publishers)
Nigeria Limited.

ISE ASETILEWA
1. Toka si atoka apola aponle ninu awon wonyi. (a) a (b) mo lo (d) nitori.
2. Ewo ni ki i se wuren ibeere apola aponle nihin-in? (a) ewo (b) nibo/ibo (d) bi i.
3. Fa ila si idi apola aponle ninu gbolohun yii: Biola n soro bi ologbon (a) Biola (b) soro bi (d) bi
ologbon.
4. Owo omode ko pepe ....... ? (a) ki o gun oke (b) ti agbalagba ko wo keregbe (d) ki agba gbe e.
5. ‘Eyin iyawo ko ni mo eni’ oro yii maa n suyo ninu asa (a) igbeyawo (b) isomoloruko (d)
ifowosowopo.

APA KEJI
1 Fa ila si idi apola aponle ninu awon wonyi:
 Ole naa ko le soro paa lagoo olopaa
 Ojo ro pupo gan-an lale ana
 Ara re ya daadaa nile iwosan nigba ti a de.
 Owo Jide tutu nini bi omi yinyin
 O fe olomoge naa kiakia nitori ewa

GSCHS/SAA KETA/J.S.S.2/YOR. Page 24

You might also like